Arẹgbẹṣọla kilọ fun Oyetọla: Ma darukọ mi sọrọ owo to o ya, iwọ ati Adeleke lẹ jọ lẹjọ
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti kilọ fun gomina ana, Alhaji Adegboyega Oyetọla, lati ma ṣe darukọ oun si wahala ẹsun obitibiti gbese ti Gomina Ademọla Adeleke fi kan ijọba rẹ. Arẹgbẹṣọla ṣalaye pe akọwe-owo nipinlẹ Ọṣun ni gbogbo akọsilẹ bi ijọba ọlọdun mẹjọ toun ṣe nipinlẹ Ọṣun ṣe yawo, ati bi wọn ṣe san an pada, oun lo si wa nipo lati ṣalaye ibi ti akanti Ọṣun de duro. Gomina Adeleke lo sọ fun awọn ori-ade nipinlẹ Ọṣun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe owo to le ni irinwo biliọnu Naira ni gbese tijọba Oyetọla fi silẹ, bẹẹ lo si ya biliọnu mejidinlogun ni kete tiṣejọba rẹ kẹnu bodo loṣu Keje, ọdun yii. Ṣugbọn Akọwe iroyin fun Oyetọla, Ismail Omipidan, sọ pe irọ funfun balau ni ọrọ ti Adeleke sọ, o ni ki wọn gbe akọsilẹ asiko ti wọn ya awọn owo naa jade, wọn yoo si mọ pe ijọba Arẹgbẹṣọla lo ti Ọṣun sinu agbami gbese. Ni ti biliọnu mejidinlogun Naira ti wọn sọ, Omipidan ṣalaye pe ijọba apapọ lo fun gbogbo ijọba ipinlẹ lowo naa laarin oṣu Kejila, ọdun 2021, si oṣu ...